Ẹ ǹlẹ́ o,
Ẹ kúu dédé àsìkò yí. Nínú àròkó yìí a ó sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa àwọ̀ ní èdè Yorùbá àti ìtúmọ̀ wọn ní ède Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn nìyìí:
Funfun – white/ cream
Dúdú – black / dark colours
Pupa – red / bright colours
Ewéko – green(ish)
Ewé – green(ish)
Wúrà – golden
Fàdákà – silver
Igi – brown
Ara – brown
Búráùn – brown
Aró – blue
Búlúù – blue
Elese àlùkò – purple
Pọ́pù – purple
Pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ – pink
Òféèfé – orange
Omi ọsàn – orange
Ìyèyè – yellow
Pupa rúsúrúsú – yellow
Yẹ́lò – yellow
Eérú – ash colour/grey
Ó dàbọ̀.
Ogbeni Oludolapo Oluseye Soboyede O kare o O gbe Igba Oroke o. O ku Ise Takuntakun Ninu Ede Yoruba. Olorun A Tubo Ma Fi Lankaye Kun Lankaye Re Loruko Jesu Amin. Ri daju pe O fi Eleyi ranse si Baba Re Ojogbon Fred Odutola ki Awon Na Le da si oro na. O se lopolopo O kare Oko mi
Omo mi owon, o ti lo jinna o. Inu mi dun wipe o gbe ede wa laruge. Se Yoruba bo won ni omo to ba so ile nu, o so apo iya ko. Lagbara Olorun a ko nii so ile nu. Mo gba fun o, omo ni o, o mo ‘we.